Yoruba Studies Review (Dec 2021)

Ìtúpalẹ̀ Ìjẹwọnúra-àṣà Nínú Àṣàyàn Oríkì Àwọn Ọba Aládé ní Ìjẹ̀bú

  • Ayọ̀bámi Mistura Tábí-Àgòrò

DOI
https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130100
Journal volume & issue
Vol. 6, no. 1
pp. 1 – 17

Abstract

Read online

Iṣẹ́ yìí gbájú mọ́ ìtúpalẹ̀ àṣàyàn oríkì àwọn ọba aládé ní ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Onírúurú iṣẹ́ ìwádìí ló ti wáyé lórí oríkì àti ipa àwọn ọba aládé láwùjọ Yorùbá, bí ó ti hàn nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iṣé tí àwọn onímọ̀ ìṣáájú ti ṣe ní ẹka-ìmọ̀ Yorùbá lápapọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn onímọ̀ náà ni wọ́n ṣe iṣẹ́ lórí oríkì àwọn ọba ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Ìwádìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn ọba ilẹ̀ Ìjẹ̀bú ni wọ́n jẹ́ bọ̀rọ̀kìnní, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú oríkì wọn. Ìwádìí yìí fi àṣàyàn oríkì àwọn ọba aládé ní ilẹ̀ Ìjẹ̀bú hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí àkóónú rẹ̀ kún fún onírúurú ìtàn nípa ètò-ìṣèlú ilẹ̀ Ìjẹ̀bú, ètò-ọrọ̀-ajé àti àṣà tí ó jẹ mọ́ ètò-ìbára-ẹni-gbépọ̀ àwùjọ Ìjẹ̀bú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà kan tó ní ọlá láwùjọ Yorùbá. Gbogbo àwọn nǹkan tí ìwádìí yìí ṣe àfàyọ rẹ̀ nínú àṣàyàn oríkì àwọn ọba aládé ilè Ìjè ̣ bú ni kò fi bẹ́ẹ̀ fara hàn nínú iṣẹ́ àwọn ̣ onímọ̀ ìṣáájú nípa oríkì ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Iṣẹ́ yìí dí àlàfo náà. Iṣẹ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé oríkì àwọn ọba aládé ilẹ̀ Ìjèbú kún fún ìtàn nípa àwùjọ wọn pẹ̀lú onírúurú àṣà ̣ àti ìṣe àwọn Ìjẹ̀bú. Iṣẹ́ yìí tún fi hàn pé, àkóónú oríkì àwọn ọba aládé ilẹ̀ Ìjẹ̀bú kún fún gbogbo ojúlówó àṣà àti ìṣe àwọn ẹ̀yà náà